1. Halleluyah, ayo wa mbo
Awon angeli t’orun mbo
Lati mu ibukun wa fun wa
K’ayo wa le ba wa dopin.
Chorus: Awa ti nwoju oluwa
K’a mase je ki are mu wa
Gbogbo wa la o ri bukun gba
Lagbara baba wa orun.
2. Halleluyah ayo wa de
Awon angeli t’orun de
‘won ti mu bukun wa fun wa
Kayo wa le ba wa dopin.
Chorus: Awa ti nwoju oluwa... Amin