1. EMI ni, mase beru,
Mo l’Emi l’Oba na,
Oba Olupese,
Ma si se foya,
Emi yio pese aini re
fun o,
Gboju re soke ki o ka irawo,
Oju Orun wo bi o le
mo iye won.
2. Aini bayi ni iru,
Omo re yio si ri,
Mase ro inu,
Emi yio f’ayo,
Ati ibukun rere fun o,
Emi li Oba ari ‘nu ri ode,
Emi Oba Olubukun
yio bu si fun o. Amin