1. B’AGOGO Orun balu,
Awa Omo Ijo Mimo
A o duro, a o duro,
Niwaju re, Niwaju Re.
Chorus: A o duro, niwaju Re,
A o b'awon angeli korin,
Ogo, ogo f’Oba wa,
Halleluya, Halleluya,
A o duro, o, niwaju Re.
2. Ijo Mimo e mura,
E damure nyin giri,
Nitori, Nitori,
Bi Jesu bade, awa o duro,
Chorus: A o duro, niwaju Re,
A o b’awon angeli korin.
Ogo, ogo f’Oba wa,
Halleluya, Halleluya,
A o ‘duro, o, niwaju Re. Amin