HYMN 708

1.  EMI ni Baba to da nyin,

     Ati awon Baba nyin

     Ta le ni na to le da nia?

     Ta o le ridi ise Mi?


2.  E mura fun ‘sura yin,

     Ti kokoro ko le je,

     Apanirun ko le de be

     Ere aiyeraiye ni.


3.  Eyi sa ni ‘sura yin,

     Iwa ati esin yin’

     Eyi ni yio gba yin la,

     Laiye yi ati l’Orun.


4.  Eyin omo ‘Jo Mimo

     E mura ke le r’ogo,

     Ti Baba ti pese fun yin,

     Ayo aiyeraiye ni.


5.  Halleluya Halleluya,

     Hossanah s’Oba Mimo

     Halleluya l’orin wa yi,

     Yio je l’ojo ‘kehin yi.


6.  Awamaridi ni,

     Ise Baba wa Orun,

     T’oda enia s’aiye yi,

     Ati eranko igbe.


7.  Ogo, ogo, ogo, ogo,

     Fun Baba Metalokan,

     B'Oti wa latetekose,

     Beni yio ma ri titi.  Amin

English »

Update Hymn