1. Oluwa, awa omo re de, Lati gbohun ebe wa soke Gegebi o ti gbo adura Elijah, Jowo gbo adura wa. 2. O gbadura kojo mase ro, Fun odun meta, on osu mefa Gegebi o ti gbo adura Elijah, Jowo gbo adura wa. 3. O si tun gbadura lekeji, Ojo ro, ile si meso wa, Gegebi o ti gbo adura Elijah, Jowo gbo adura wa. 4. Adura lo n silekun anu, Adura lo si Anna ninu, Gegebi o ti gbo adura Elijah, Jowo gbo adura wa. Amin